Friday, March 26, 2010

Iṣẹ́ ni òògùn ìṣẹ́

Iṣẹ́ ni òògùn ìṣẹ́,
Múra sí iṣẹ́ rẹ ọrẹẹ mi.
Iṣẹ́ ni a fií ndi ẹni gíga.
Bí a kò bá rẹni fẹyìn tì,
Bí òlẹ làá rí.
Bí a kò bá rẹni gbẹkẹlẹ,
À tẹra mọ iṣẹ́ ẹni.
Ìyá rẹ lè lówó lọwọ,
Ki bàbá rẹ sì lè lẹsin lékan,
Bí o bá gbójú lé wọn;
O tẹ tán ni mo sọ fún ọ.
Ohun tí a kò bá jìyà fún,
Kìí lè tọjọ.
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ fún,
Níí pé lọwọ ẹni.
Apá lará, ìgùnpá nì’yekan.
Bí ayé ba nfẹ ọ lónìí,
Bí o bá lówó lọwọ ní,
Wọn á máa fẹ ọ lọla.
Tàbí tí o bá wà ní ipò àtàtà,
Ayé á yé ọ sí tẹrin-tẹrin,
Jẹ kí o di ẹni ti nráágó,
Kí o rí báyé tií yímú sí ọ.
Ẹkọ sì tún nsọnií dọgá,
Múra kí o kọọ dáradára.
Bí o sì rí ọpọ ènìyàn,
Tí wọn nfi ẹkọ ṣe èrín rín,
Dákun má ṣe f’ara wé wọn.
Ìyà nbọ f’ọmọ tí kò gbọn,
Ẹkún nbẹ f’ọmọ tó nsá kiri.
Má f’òwúrọ ṣeré, ọrẹẹ mi,
Múra ṣiṣẹ, ọjọ nlọ.

1 comment:

  1. Kindly please translate the poem into English, please!!

    ReplyDelete