Tuesday, March 23, 2010

Amuyẹ fun titumọ ede

Olutumọ ede gbọdọ ni oye pipe nipa ohun ti onkọwe ede ti o ntumọ nsọ ati ete ti onkọwe ni.

Olutumọ ede gbọdọ ni oye pipe nipa ede ti o ntumọ si ati oye ti o tayọ nipa ede ti a fi kọwe eyiti o ntumọ.

Olutumọ ede gbọdọ yẹra fun titumọ ede nipa lilo ọrọ fun ọrọ nitori ṣiṣe eyi le da erongba onkọwe ọrọ ti a tumọ si ede miran ru.

Olutumọ ede gbọdọ lo ede ti o wọpọ ki ọrọ ti o ntumọ baale le ye awọn oluka rẹ.

Nipa tito ọrọ ti o ba yan, olutumọ ede gbọdọ gbiyanju lati jẹ ki ọrọ ti ohun ntumọ ni iro ati ipa ti o tọ.

No comments:

Post a Comment