Thursday, September 23, 2010

Ẹrin musẹ kan

O rẹrin musẹ kan si ajeji kan ti inu rẹ ko dun. Ẹrin naa jẹ ki ara ajeji naa ya. O ranti awọn oore atijọ kan ti ọrẹ rẹ ṣe fun-un, o si kọ lẹta idupẹ kan sii. Inu ọrẹ yii dun to bẹẹ gẹ fun lẹta idupẹ yii ti o fi fi owo gọbọyi t’ọrẹ fun agbe-ounjẹ lẹyin ti o jẹun tan. Ẹnu ya agbe-ounjẹ fun owo gọbọyi yii, ti o fi fi gbogbo rẹ ta tẹtẹ. Ni ọjọ keji, o gba owo bibori tẹtẹ ti o ta, o si fun ọkunrin kan l’oju popo lara rẹ. okunrin oju popo naa dupẹ; o si jẹun fun ọjọ meji ti ko ti fi ri nkankan jẹ. Lẹyin ti o jẹun tan, o lọ si ile-kereje rẹ, ko si mọ ni igba naa ewu ti ohun yoo koju.
Li ọna, o gbe ọmọ-aja kan ti otutu nmu ki o baa le ya ooru ni ile rẹ. Inu aja naa dun lati kuro ninu iji. Ni alẹ ọjọ naa, ile gba ina. Ọmọ aja naa gbo bii [aago] itaniji o gbo titi o fi ji gbogbo ara ile, o si gba wọn lọwọ ewu. Ọkan lara awọn ọmọde-kunrin ti a gbala dagba, o si di Olori orile-ede. Gbogbo eleyi nitori wipe ẹnikan rẹrin musẹ ti ko kasi kan ti ko si naa ni owo kankan.

Ivan Minic
http://my.opera.com/SerbianFighter/blog/show.dml/70109

Translated by Biodun

No comments:

Post a Comment