Thursday, September 23, 2010

Ṣiṣe Iṣẹ Daradara (Job Quality Control).

Ohun kan ti o ṣe pataki nipa ṣiṣe iṣẹ olutumọ ede ni lati ṣee iṣẹ naa daradara (quality). Opọlọpọ igba ti mo ba ni lati yẹ iṣẹ kan wo, ti mo si rii wipe a ko ṣe iṣẹ naa daradara, ara mi maa nbu m’aṣọ. O jẹ ohun ti yoo mu ki iṣẹ eniyan dayatọ gedegbe si ti awọn ẹlomiran bi eniyan, gẹgẹ bii olutumọ ede ba tiraka tabi gbiyanju lati ṣe iṣẹ ti o ba ri gba daradara. Awọn ti o ma ngbe iṣẹ (atumọ ede fun eniyan) ma nsaba gbe iṣẹ ti olutumọ ede ba ba wọn ṣe lọ fun olutumọ ede miiran lati ṣe ayẹwo boya olutumọ ede ba ṣe iṣẹ naa doju aami tabi oju oṣuwọn. Bi o ba ṣe iṣẹ ti o ri gba daradara, awọn eniyan ti o ngbe iṣẹ fun ọ yii yoo ni ifọkọtan ninu rẹ, wọn yoo si gbe iṣẹ wa ni igba miiran. Ṣugbọn bi o ba gba iṣẹ ti o ko ṣee bi o ti yẹ, ti wọn si gbe lọ fun ayẹwo ti wọn ri gbogbo koba-kogbe inu iṣẹ naa, ti wọn tun ni lati san owo miiran fun ẹlomiran lati tun ṣe, wọn yoo woye wipe olutumọ ede naa ko kun oju oṣuwọn, wọn ko si ni gbe iṣẹ wa mọ. Ni ọpọlọpọ igba, awọn ẹlomiran ti wọn ba fẹ gbe iṣẹ fun ọ yoo fẹ mọ awọn ti o ti ba ṣiṣẹ ri, ti wọn yoo si ko’we lati beere lọwọ wọn bi iṣẹ rẹ gẹgẹ bi olutumọ ede ṣe ri. Bi o ba si ṣe ṣe iṣẹ wọn ni wọn yoo ti wi, wọn ko ni bo ‘aṣiri’ rẹ rara.

Ohun miiran ti o tun ṣe koko ni ki o ri wipe o da iṣẹ naa ti o ri gba pada ni akoko ti o ba da lati daa pada tabi akoko ti wọn ṣeto wipe ki o daa pada. Akoko ṣe pataki. Maṣe fi ṣofo rara. Bi o ba ri iṣe kan gba gẹgẹbii olutumọ ede, rii daju wipe o ṣe e daradara ki o si da pada l’akoko, ki o ba le niyi lọwọ awọn ti o ngbe iṣẹ fun ọ.

Bi o ba nilo alaye siwaju sii, fi iwe ranṣẹ si bodunley@gmail.com

Ẹrin musẹ kan

O rẹrin musẹ kan si ajeji kan ti inu rẹ ko dun. Ẹrin naa jẹ ki ara ajeji naa ya. O ranti awọn oore atijọ kan ti ọrẹ rẹ ṣe fun-un, o si kọ lẹta idupẹ kan sii. Inu ọrẹ yii dun to bẹẹ gẹ fun lẹta idupẹ yii ti o fi fi owo gọbọyi t’ọrẹ fun agbe-ounjẹ lẹyin ti o jẹun tan. Ẹnu ya agbe-ounjẹ fun owo gọbọyi yii, ti o fi fi gbogbo rẹ ta tẹtẹ. Ni ọjọ keji, o gba owo bibori tẹtẹ ti o ta, o si fun ọkunrin kan l’oju popo lara rẹ. okunrin oju popo naa dupẹ; o si jẹun fun ọjọ meji ti ko ti fi ri nkankan jẹ. Lẹyin ti o jẹun tan, o lọ si ile-kereje rẹ, ko si mọ ni igba naa ewu ti ohun yoo koju.
Li ọna, o gbe ọmọ-aja kan ti otutu nmu ki o baa le ya ooru ni ile rẹ. Inu aja naa dun lati kuro ninu iji. Ni alẹ ọjọ naa, ile gba ina. Ọmọ aja naa gbo bii [aago] itaniji o gbo titi o fi ji gbogbo ara ile, o si gba wọn lọwọ ewu. Ọkan lara awọn ọmọde-kunrin ti a gbala dagba, o si di Olori orile-ede. Gbogbo eleyi nitori wipe ẹnikan rẹrin musẹ ti ko kasi kan ti ko si naa ni owo kankan.

Ivan Minic
http://my.opera.com/SerbianFighter/blog/show.dml/70109

Translated by Biodun