Gbogbo iṣẹ ni o ni iyi tirẹ. Iṣẹ olutumọ ede jẹ iṣẹ ti o dara. Iṣẹ ole ni o ba ọmọ jẹ, gẹgẹ bi awọn Yoruba ti ṣe ma nsọ. Iṣẹ olutumọ ede jẹ iṣẹ ti yoo fun eniyan ni anfaani lati le ṣe nkan miiran. Yoo fun eniyan ni owo ati ifọkanbalẹ pẹlu, ṣugbọn kii ṣe owo ọfẹ rara. Owo ti eniyan yoo ṣiṣẹ fun ni. Owo ti o nwa lati ibi ki eniyan tumọ ede kii ṣe owo awufuu. Eniyan nlati ṣiṣẹ ki o to le ri owo gba ni. Bi o ba ṣiṣẹ fun eniyan kan, o le to laarin osẹ meji, oṣu kan, oṣu mẹta tabi ju bẹẹ lọ ki eniyan to ri owo gba. Eyi dale lori akọsilẹ ile-iṣẹ ti eniyan baa ṣiṣẹ ba ṣe ri.
Bawo ni eniyan ti ṣe le ṣe iṣẹ olutumọ ede? Ikinni ni lati mọ ede abinibi ẹni sọọ ati lati le kọọ daradara. Ekeji ni lati mọ ibiti iṣẹ ti eniyan fẹ ṣe naa wa. Bawo ni eniyan yoo ṣe ti ri awọn iṣẹ wọnyii? Orilẹ-ede Naijiria jẹ eyiti o tobi pupọ ti o si ni awọn anfaani ti o pọ lọpọ yanturu bakanna. Ọpọlọpọ awọn orile-ede ti wọn nṣe ohun kan tabi omiran ni wọn nfẹ lati taa ni orilẹ-ede wa. Ọna kan pato lati jẹ ki awọn ọja wọn wọnyii ta tabi niyi ni oju awọn eniyan wa ni lati kọọ ni ede abinibi awọn eniyan wa, paapaa ni awọn ede mẹta ti o wọpọ julọ ni orilẹ-ede wa: Hausa, Yoruba ati Igbo.
Ibiti eniyan yoo ti ri ọpọlọpọ awọn iṣẹ yii ni lori ayelujara (Internet). Awọn ipo kan wa lori ayelujara ti awọn eniyan ti wọn ni iṣẹ kan tabi omiran lati ṣe ti wọn ti maa nfi lọ pe awọn nwa eniyan ti oni-imọ lati ṣee. Ọkan ninu awọn ibi ti eniyan ti le ri awọn iṣẹ wọnyi ni www.proz.com, tanslationdirectory.com, traduguide.com ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eniyan yoo ni lati kọkọ fi orukọsilẹ lori ipo yii ki eniyan to le gba iṣẹ nibẹ. A ni awọn ti o nsan owo lati fi orukọ silẹ ni ipo ayelujara yii bẹẹ si ni awọn ti kii san owo wa. Awọn ti o ba nsan owo ni awọn anfaani kan ti ẹni ti kii san owo ko ni, ti ko si le ni rara. Tẹlẹ tẹlẹ bakanna, ẹniti o ba forukọsilẹ ni ipo yi le gba iṣẹ laijẹ ọmọ ẹgbẹ ti o nsan owo. Ṣugbọn ki o to le gba iṣẹ lori ipo yii nisinyi owo dola kan ($1) ni eniyan yoo fi ja (bid) fun iṣẹ yii.